Yorùbá

ÌTẸ́LỌ́RÙN

Ìrètí wo ló wà bí kò ṣe ìrètí Mi?
Ìṣírí wo ló wà
  bí kò ṣe ìṣírí Mi?
Ìfẹ́ wo ló lágbára ju tèmi lọ?

Èémí afẹ́fẹ́ kan pàápàá kò ní ìtumọ̀
  láìsí ìtọ́nisọ́nà Mi.
Ìṣẹ́jú kan pàápàá nínú ọjọ́ rẹ kò níye lórí
  láìsí ìdarí Mi.

Tẹ̀ lé ọ̀nà Mi, kí o sì rí ọ̀nà rẹ.
Wá àwọn ọ̀nà tí Mo ń gbà, kí o sì lóye ọ̀nà tí ò ń gbà.
Gba ọ̀rọ̀ Mi, kí o sì mọ ètò Mi.

Kò sí ìṣẹ́jú-àáyá kan tí ó ń kọjá
  láìjẹ́ pé Mo ń rí ọ.
Mo wà nínú rẹ nígbà gbogbo.
Wá láti wà níwájú Mi
  kí o sì mọ̀ pé Mo wà pẹ̀lú rẹ.
Ṣe àkíyèsí ìwà Mi
  kí o sì mọ̀ pé Mo bìkítà fún ọ.
Jẹ́ kí ìwà Mi yí àkókò rẹ ká
  láti mú ìtẹ́lọ́rùn wá fún ọ
  àti ìtẹ́lọ́rùn ọkàn bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọjá.

Àṣàrò Tó Kàn

Àtòjọ Àkóónú