Yorùbá

Ààwẹ̀ àti Àìjẹ Ẹran

Ọjọ́rú Eérú àti Ọjọ́ Ẹtì Rere jẹ́ ọjọ́ tí ààwẹ̀ àti àìjẹ ẹran jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn Kátólíìkì. Ní àfikún, àwọn ọjọ́ Ẹtì ní àsìkò Ààwẹ̀ Ọjọ́ Ogójì jẹ́ ọjọ́ tí àìjẹ ẹran jẹ́ ọ̀ranyàn.

Fún àwọn ọmọ Ìjọ Kátólíìkì ti Látìnì, àwọn ìlànà ààwẹ̀ jẹ́ ọ̀ranyàn láti ọmọ ọdún 18 títí dé ọmọ ọdún 59. Nígbà ààwẹ̀, a gba ènìyàn láàyè láti jẹ oúnjẹ àjẹyó lẹ́ẹ̀kan, àti oúnjẹ díẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì tí àpapọ̀ wọn kò tó oúnjẹ àjẹyó ẹ̀ẹ̀kan. Àwọn ìlànà nípa àìjẹ ẹran jẹ́ ọ̀ranyàn fún àwọn ọmọ Ìjọ Kátólíìkì ti Látìnì láti ọmọ ọdún 14 lọ

Àwọn ọmọ Ìjọ Kátólíìkì ti Ìlà Oòrùn gbọ́dọ̀ pa òfin pàtó ti Ìjọ tiwọn tó ní àṣẹ láti ṣàkóso ara rẹ̀ mọ́.

Bí ó bá ṣeé ṣe, a máa ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ààwẹ̀ Ọjọ́ Ẹtì Rere títí dé Ìṣọ́ Àjíǹde (ní alẹ́ Ọjọ́ Àbámẹ́ta Mímọ́) gẹ́gẹ́ bí “ààwẹ̀ Àjíǹde” láti bọ̀wọ̀ fún ìjìyà àti ikú Olúwa Jésù, àti láti múra ara wa sílẹ̀ láti ní ìpín kíkún sí i nínú Àjíǹde rẹ̀ àti láti ṣayẹyẹ rẹ̀ pẹ̀lú ìmúratán sí i.


Orísun: usccb.org