Baba, mo ya ọjọ́ tuntun yìí sí mímọ́ fún Ọ;
bí mo ṣe ń ṣe iṣẹ́ mi.
Mo bẹ Ọ pé kí O bù kún àwọn tí mo bá pàdé.
Olúwa, mo gbàdúrà fún gbogbo àwọn ọkùnrin àti obìnrin
tí ń ṣiṣẹ́ láti rí ohun àmúṣọrọ̀ wọn;
fún wọn ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ohun tí wọ́n ń ṣe.
Ẹ̀mí Ọlọ́run,
tu àwọn aláìníṣẹ́ àti àwọn ìdílé wọn nínú;
ọmọ Rẹ ni wọ́n, wọ́n sì jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi.
Mo bẹ Ọ pé kí O ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí iṣẹ́ láìpẹ́.
Àmín.
Láti ọwọ́ Ignatius Loyola Mímọ́