Yorùbá

Ẹ̀BẸ̀ KAN

Béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Mi, nítorí pé ó wà fún ọ.
Má bẹ̀rù ohun tí ó ń dúró dè ọ,
  nítorí pé Èmi kì yóò jẹ́ kí ìpalára kankan dé bá ọ.

Mú ẹ̀bẹ̀ rẹ wá sí ìtẹ́ Mi,
  Èmi yóò sì mú ìfẹ́-ọkàn rẹ ṣẹ.
Mo jẹ́ ọ̀làwọ́ sí ọ,
  nítorí pé Mo bìkítà nípa bí ayọ̀ rẹ ṣe ń tẹ́ ọ lọ́rùn.

Ohun tí ó ṣe pàtàkì kì í ṣe ohun tí àwọn ẹlòmíràn sọ pé ó dára fún ọ
  bí kò ṣe ìfẹ́-ọkàn tí o ní sí Mi.
Jẹ́ kí ìfẹ́-ọkàn rẹ sí Mi ṣamọ̀nà rẹ
  láti ipò pípa ara rẹ mọ́
  sí ipò ìyánhànhàn gbangba fún wíwà Mi.

Àṣàrò Tó Kàn

Àtòjọ Àkóónú