Yorùbá

MO WÀ PẸ̀LÚ RẸ NÍGBÀ GBOGBO

Àwọn iyèméjì rẹ
  yóò fọ́ ọ lójú.
Àwọn ìbẹ̀rù rẹ
  yóò dí ọ lọ́wọ́.
Àìpinnu rẹ
  yóò mú ọ ṣìnà.

Dá àwọn ìṣòro wọ̀nyí
  padà fún Ẹlẹ́dàá wọn.

Ìfẹ́-ọkàn rẹ sí ìwà Mi
  yóò mú ọ rí i.

Wíwá tí o ń wá
  yóò jẹ́ kí o rí Mi.

Níní sùúrù pẹ̀lú ìwà rẹ
  yóò jẹ́ kí o lóye ìwà Mi.

Ìwọ yóò mọ̀ pé Mo wà níbẹ̀
  nígbà tí o bá ṣí ọkàn rẹ sí ìwà Mi.

Bèèrè fún Mi,
  Èmi yóò sì rí ọ.

Na ọwọ́ rẹ sí Mi,
  Èmi yóò sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ.

Kò sí ìṣẹ́jú àáyá kan
  tí yóò kọjá fún ọ láìsí Mi.
Kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí yóò bẹ̀rẹ̀
  tí yóò sì parí láìsí Mi pẹ̀lú rẹ.

Àṣàrò Tó Kàn

Àtòjọ Àkóónú