Gemäldegalerie Berlin, ohun ìní gbogbo ènìyàn, láti Wikimedia Commons
Baba,
Mo fi ara mi lé Ọ lọ́wọ́;
ṣe ohun tí Ó bá fẹ́ pẹ̀lú mi.
Ohunkóhun tí Ó bá ṣe, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Rẹ:
Mo múra tán fún ohun gbogbo, mo gba ohun gbogbo.
Jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ nìkan ṣẹ nínú mi,
àti nínú gbogbo àwọn ẹ̀dá Rẹ Ìtumọ̀ Yorùbá: –
Èmi kò fẹ́ ju èyí lọ, Olúwa.
Mo fi ẹ̀mí mi lé Ọ lọ́wọ́:
Mo fi í fún Ọ pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi,
nítorí mo nífẹ̀ẹ́ Rẹ, Olúwa, nítorí náà mo nílò láti fi ara mi fún Ọ,
láti fi ara mi lé Ọ lọ́wọ́ láìfi ohunkóhun sẹ́yìn,
àti pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé tí kò ní ààlà,
nítorí Ìwọ ni Baba mi.
Àmín.
Charles de Foucauld Mímọ́
